Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:60-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

60. Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ?”

61. Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́.Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ò ní, “Ṣé ìwọ ni Kírísítì náà, Ọmọ Ọlọ́run?”

62. Jésù wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ-Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọ̀sánmọ̀ ojú ọ̀run.”

63. Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rí fún?

64. Ẹ̀yin fúnra yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ìkú.”

65. Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ̀ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń gbà a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùsọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

66. Ní àkókò yìí Pétérù wà ní ìṣàlẹ́ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsí í tí Pétérù ń yáná.

67. Nigba tí ó rí Pétérù tí ó ti yáná, Ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ gbangba pé,“Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jésù ara Násárẹ̀tì.”

68. Ṣùgbọ́n Pétérú ṣẹ́, ó ni, “N kò mọ Jésù náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Pétérù sì jáde lọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.

69. Ọmọbìnrin yẹn sì tún rí Pétérù. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù.”

70. Ṣùgbọ́n Pétérù tún ṣẹ́.Nígbà tí ó sí tún ṣẹ díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Pétérù wá wí fún un pé, “Láìṣe àní àní, ara wọn ni ìwọ. Nítorí ará Gálílì ni ìwọ náà.”

71. Nígbà náà ni Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”

72. Lójú kan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Pétérù rántí ọ̀rọ̀ Jésù fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò ṣẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkùn.

Ka pipe ipin Máàkù 14