Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:35-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.

36. Ó sì wí pé, “Á bà Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò se èyí tí ìwọ fẹ́.”

37. Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Pétérù pé, “Símónì, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan?

38. Ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39. Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.

40. Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ì bá fún un.

41. Ó sì wá nígbà kẹ́ta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́.

42. Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòòsí!”

43. Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Júdásì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ́ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbààgbà Júù ni ó rán wọn wa.

44. Júdásì tí fí àmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jésù, Ẹ mú un.”

45. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, Júdásì lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrá, ó wí pé, “Rábì!” ó sì fi ẹnu kò Jésù lẹ́nu.

46. Wọ́n sì mú Jésù.

47. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró idà rẹ̀ yọ, ó fi sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ge etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.

48. Nígbà náà Jésù dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú?

49. Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹ́ḿpìlì, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.”

Ka pipe ipin Máàkù 14