Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 13:20-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. À fi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.

21. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kírísítì nìyìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.

22. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹ́tàn àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tàn àwọn ọmọ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

23. Nítorí náà, ẹ sọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!

24. “Ṣùgbọ́n ni ọjọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn ìpọ́njú tí mo sọ yìí,“ ‘òòrùn yóò sókùnkùn,òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

25. Àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú yóò já lulẹ̀ láti ojú ọ̀run.Ṣánmọ̀ àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀ yóò wárìrì.’

26. “Nígbà náà ni gbogbo ayé yóò sì rí i tí Èmi Ọmọ-Ènìyàn yóò máa bọ̀ wá láti inú àwọ̀sánmọ̀pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.

27. Nígbà náà ni yóò sì rán àwọn ańgẹ́lì rẹ láti kó àwọn àyànfẹ ní gbogbo ayé jọ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aye láti ìkángun ayé títí dé ìkangun ọ̀run.

28. “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ kan lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ titun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fi hàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé.

29. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí àwọn ohun abàmì wọ̀n-ọn-nì tí mo ti sọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tan, lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

30. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, Iran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ

31. Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.

32. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn ańgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n. Ọlọ́run Baba nìkan ló mọ̀ ọ́n.

33. Ẹ máa sọra, Ẹ má ṣe sùn kí ẹ sì máa gbàdúrà: nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà ní ó àkókò ná yóò dé.

Ka pipe ipin Máàkù 13