Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 13:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí Jésù ti ń jáde láti inú tẹ́ḿpìlì ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”

2. Jésù dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

3. Bí Jésù ti jókòó níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olífì tí ó rékọjá àfonífojì láti Jerúsálémù, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Ańdérù wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkòkọ̀ pé,

4. “Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ḿpílì náà? Kí ni yóò sì jẹ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”

5. Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tan yín.

6. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ni orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kírísítì,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ́.

7. Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.

8. Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba ilẹ̀ yóò máa jin ni ibi púpọ̀. Ìyàn yóò sì wà níbi gbogbo. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú tí ń bọ̀ níwájú.

9. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyè sára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú tẹ́ḿpìlì wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn gómìnà àti níwájú àwọn ọba pẹ̀lú, nítorí tí ẹ jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

10. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀ èdè kí òpin tó dé.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú yín, tí ẹ sì dúró níwájú adájọ́, ẹ má ṣe dààmú nípa ohun tí ẹ ó wí fún ààbò. Ẹ ṣáà sọ ohun tí Ọlọ́run bá fi sí yín lọ́kàn. Ẹ̀yin kọ́ ní yóò sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

12. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣekú pa òbí wọn.

13. Àwọn ènìyàn yóò kórira yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.

14. “Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró ní bí tí kò tọ́, tí a tí ẹnu wòlíì Dáníẹ́lì sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Jùdíà sá lọ sí orí òkè.

15. Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọkalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má si ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Máàkù 13