Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 12:12-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olúkọ̀ òfin pẹ̀lú àwọn àgbààgbà fẹ́ mú Jésù lákókò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.

13. Ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn Farisí pẹ̀lú àwọn kan tí í ṣe ọmọ-ẹ̀yìn Hẹ́rọ́dù wá sọ́dọ̀ Jésù, láti fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, títí yóò fi sọ ohun kan kí wọn lè rí fi mú.

14. Bí wọn ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ máa ń sọ òtítọ́ tìrẹ láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwọ máa ń kọ́ni. Nísinsin yìí, sọ fún wa, ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti máa san owó orí fún Késárì?

15. Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?” Ṣùgbọ́n Jésù mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.”

16. Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Késárì ni.”

17. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Késárì fún Késárì. Ṣùgbọn ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.

18. Àwọn Ṣadusí tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé,

19. “Olùkọ́, Mósè fún wa ní òfin pé: Nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.

20. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan wà, èyí tí ó dàgbà jùlọ gbéyàwó, ó sì kú láìbímọ.

21. Arákùnrin rẹ̀ kejì ṣu obìnrin tí ó fi sílẹ̀ lópó, láìpẹ́, òun pẹ̀lú tún kú láìbímọ. Arákùnrin kẹta tó sú obìnrin yìí lópó tún kú bákan náà láìbímọ.

Ka pipe ipin Máàkù 12