Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 6:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Símónì (ẹni tí a pè ní Pétérù) àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, Jákọ́bù àti Jòhánù, Fílípì àti Batolóméù.

15. Mátíù àti Tọ́másì, Jákọ́bù ọmọ Álíféù, àti Símónì tí a ń pè ní Ṣélótè,

16. Àti Júdà arákùnrin Jákọ́bù, àti Júdásì Ísíkáríótù tí ó di ọ̀dàlẹ̀.

17. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọpọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Jùdéà, àti Jerúsálémù, àti agbègbè Tírè àti Ṣídónì, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú àrùn wọn;

18. Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́; ni ó sì mú láradá.

19. Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.

20. Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ èyìn rẹ̀, ó ní:“Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòsì,nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.

21. Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń panísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yòó.Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ńsọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.

22. Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kóríra yín,tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín,tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú, nítorí ọmọ ènìyàn.

23. “Kí ẹ̀yin yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ̀yin sì fò sókè fún ayọ̀, nítorí tí ẹ̀yin ti gba ìtùnú yín ná.

24. “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.

25. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,nítorí ebi yóò pa yín,Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.

26. Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wòlíì.

27. “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀ta yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín;

28. Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín.

29. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, pa èkejì dà sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù rẹ pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Lúùkù 6