Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 24:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.

10. Màríà Magaléènì, àti Jóánnà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn àpósítélì.

11. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.

12. Nígbà náà ni Pétérù dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnrarawọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

13. Sì kíyèsí i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ijọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Èmáúsì, tí ó jìnnà sí Jerúsálémù níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.

14. Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.

15. Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jésù tìkara rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.

16. Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

17. Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kínni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?”Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.

18. Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kíléópà, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sáà ni ìwọ ní Jerúsálémù, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

19. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jésù ti Násárẹ́tì, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,

20. Àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélèbú.

21. Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Ísírẹ́lì ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹ́ta tí nǹkan wọ̀nyí ti sẹlẹ̀.

22. Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá dá wa níjì:

23. Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè.

Ka pipe ipin Lúùkù 24