Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 2:15-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn Olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tàrà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀ jẹ, tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.”

16. Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọ-ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.

17. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.

18. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.

19. Ṣùgbọ́n Màríà pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.

20. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

21. Nígbà tí ijọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ańgẹ́lì náà wá kí á tó lóyún rẹ̀ nínú.

22. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Màríà sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, Josefu àti Màríà gbé Jésù wá sí Jerúsálémù láti fi í fún Olúwa;

23. (Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),

24. àti láti rúbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “àdàbà méjì tàbí ẹyẹlẹ́ méjì.”

25. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálémù, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣíméónì; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Ísírẹ́lì: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

26. A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí kírísítì Olúwa.

27. Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹ́ḿpìlì: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé ọmọ náà Jésù wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin,

Ka pipe ipin Lúùkù 2