Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 13:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fù ú, tí ó bá sí ìlẹ̀kùn ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’

26. “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú.’

27. “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’

28. “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.

29. Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà òòrùn, àti ìwọ̀-òòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.

30. Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni ìwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”

31. Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhín-ín yìí: nítorí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ pa ọ́.”

32. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsí i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lóní àti lọ́la, àti ní ijọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’

33. Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lóní, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ pé wòlíì yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerúsálémù.

34. “Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!

35. Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro: lóòtóọ́ ni mo sì wí fún yín, Ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”

Ka pipe ipin Lúùkù 13