Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 10:18-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Sátánì ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá.

19. Kíyèsí i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèé mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì sí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára.

20. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ sí èyí, pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

21. Ní wákàtí kan náà Jésù yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sáà yẹ ní ojú rẹ.

22. “Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

23. Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apákan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí.

24. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

25. Sì kíyèsí i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kínni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26. Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Bí ìwọ ti kà á?”

27. Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘Ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

28. Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere: ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29. Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jésù wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30. Jésù sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán.

31. Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà: nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì.

32. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì.

Ka pipe ipin Lúùkù 10