orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹyin olúwa, ẹ má a fi èyí tí ó tọ́ tí ó sì dọ́gba fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ yín; kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ni owa kan ní ọ̀run.

Àwọn Ìlànà fún Ìjọ

2. Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́;

3. Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣílẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kírísítì, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú:

4. Ẹ gbàdúrà pé kí èmí leè máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi.

5. Ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n ni tí bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ńbẹ̀ lóde, kí ẹ sì máa ra ìgbà padà.

6. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá òlúkulùlku ènìyàn lóhùn.

Àwọn Ìníni Ìkẹ̀yìn

7. Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikíkú yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀ gbogbo bí nǹkan tirí nípa mi. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòótọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa:

8. Ẹni tí èmí ń rán sí yín ńitorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọ̀kàn yín nínú;

9. Òun sì ń bọ̀ pẹ̀lú Ónísímù, arákùnrin olóòótọ́ àti olùfẹ́, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú yín. Àwọn ní yóò sọ ohun gbogbo tí à ń ṣe níhìn-ín-yìí fún un yín.

10. Árísítákù, ẹlẹgbẹ́ mí nínú túbú kí i yín, àti Máàkù, ọmọ arábìnrin Bánábà (Nípaṣẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ti gba àṣẹ; bí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ gbà á).

11. Àti Jésù, ẹni tí à ń pè ní Jọsítọ́sì, ẹni tí ń ṣe ti àwọn onílà. Àwọn wọ̀nyí nìkan ni olùbá ṣiṣẹ́ mí fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹni tí ó tí já sí ìtùnú fún mi.

12. Épáfúrà, ẹni tí ń ṣe ọ̀kan nínú yín àtiìránṣẹ́ Kírísítì kí í yín. Òun fí ìwàyájà gbàdúrà nígbà gbogbo fún-ún yín, kí ẹ̀yin kí ó lè dúró ní pípé nínú ohun gbogbo nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

13. Nítorí mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ń ṣisẹ́ kárakára fún yín, àti fún àwọn tí ó wà ní Laodékíà, àti àwọn tí ó wà ní Hírápólì.

14. Lúùkù, aràkùnrin wa ọ̀wọ́n, oníṣègùn, àti Dẹ́mà ki í yín.

15. Ẹ kí àwọn ará tí ó wà ńi Laodékíà, àti Nímífásì, àti ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.

16. Nígbà tí a bá sì ka ìwé yìí ní àárin yín tan, kí ẹ mú kí a kà á pẹ̀lú nínú ìjọ Laodékíà; ẹ̀yin pẹ̀lú sì ka èyí tí ó ti Laodékíà wá.

17. Kí ẹ sì wí fún Áríkípù pé, “Kíyèsi iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ìwọ ti gbà nínú Olúwa kí o sì ṣe é ní kíkún.”

18. Ìkíni láti ọwọ́ èmi Pọ́ọ̀lù. Ẹ máa ránti ìdè mi. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín. Àmín. A kọ ọ́ láti Rómù lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Kólósè láti ọwọ́ Tíkíkù àti Ónísímù.