Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 9:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.

2. Àwọn Ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Olùkọ́, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

3. Jésù dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a baà lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lara rẹ̀.

4. Àwa ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó ba ti jẹ́ ọ̀sán: òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.

5. Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

6. Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà pa ojú afọ́jú náà.

7. Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Sílóámù!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.

8. Ǹjẹ́ àwọn aládúgbò àti àwọn tí ó rí i nígbà àtijọ́ pé alágbe ni ó jẹ́, wí pé, “Ẹni tí ó ti ń jókòó ṣagbe kọ́ yìí?”

9. Àwọn kan wí pé òun ni.Àwọn elòmíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ó jọ ọ́ ni.”Ṣùgbọ́n òun wí pé, “Èmi ni.”

10. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Bá wo ni ojú rẹ ṣe là?”

11. Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jésù ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kùn mí lójú, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Sílóámù, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

12. Wọ́n sì wí fún un pé, “Òun náà ha dà?”Ó sì wí pé, “Èmi kò mọ̀.”

13. Wọ́n mú ẹni tí ojú rẹ̀ ti fọ́ rí wá sọ́dọ̀ àwọn Farisí.

14. Ọjọ́ ìsinmi ni ọjọ́ náà nígbà tí Jésù ṣe amọ̀, tí ó sì là á lójú.

15. Nítorí náà àwọn Farisí pẹ̀lú tún bi í léèrè, bí ó ti ṣe ríran. Ọkùnrin náà fèsìì, “Ó fi amọ̀ lé ojú mi, mo sì wẹ̀, báyìí mo sì ríran.”

16. Nítorí náà àwọn kan nínú àwọn Farisí wí pé, “Ọkùnrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, nítorí tí kò pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.”Àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ọkùnrin tí í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò ha ti ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ àmì wọ̀nyí?” Ìyapa sì wà láàárin wọn.

17. Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ wí nítorí rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?”Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”

Ka pipe ipin Jòhánù 9