Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 21:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jésù fẹ́ràn wí fún Pétérù pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Símónì Pétérù gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú òkun.

8. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja.

9. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yinná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.”

11. Nítorí náà Símónì Pétérù gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́taléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya.

12. Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.

13. Jésù wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja.

14. Èyí ni Ìgbà kẹ́ta nísinsin yìí tí Jésù farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

15. Ǹjẹ́ lẹ́yìn, ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

16. Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Símónì ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi bí?”Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17. Ó wí fún un nígbà kẹ́ta pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ràn mi bí?”Inú Pétérù sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹ́ta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Jésù wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

18. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ ó na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.

Ka pipe ipin Jòhánù 21