orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ikú Lásárù

1. Ara ọkùnrin kan sì ṣe aláìdá, Lásárù, ará Bẹ́tẹ́nì, tí í ṣe ìlú Màríà àti Màta arábìnrin rẹ̀.

2. (Màríà náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lásárù í ṣe, ara ẹni tí kò dá.)

3. Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ ránsẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”

4. Nígbà tí Jésù sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”

5. Jésù sì fẹ́ràn Màta, àti arábìnrin rẹ̀ àti lásárù.

6. Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà.

7. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Jùdíà.”

8. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rábì, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”

9. Jésù dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí.

10. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”

11. Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lásárù ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

12. Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá se pé ó sùn, yóò sàn.”

13. Ṣùgbọ́n Jésù ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.

14. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn gbangba pé, Lásárù kú,

15. Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀, Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

16. “Nítorí náà Tómásì, ẹni tí à ń pè ní Dídímù, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”

Jésù Tu Àwọn Arábìnrin Rẹ̀ Nínú

17. Nítorí náà nígbà tí Jésù dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ijọ́ mẹ́rin ná,

18. Ǹjẹ́ Bétanì sún mọ́ Jérúsálẹ́mù tó ibùsọ Mẹ́ẹ̀dógún:

19. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Màta àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.

20. Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé.

21. Nígbà náà, ni Màta wí fún Jésù pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

22. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23. Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24. Màta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25. Jésù wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè:

26. Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27. Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.”

29. Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

30. Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Màrta ti pàdé rẹ̀.

31. Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.

32. Nígbà tí Màríà sì dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbáṣe pé ìwọ ti wà níhín-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”

33. Nígbà tí Jésù rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́.

34. Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”

35. Jésù sọkún.

36. Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”

37. Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣeé kí ọkùnrin yìí má kú bí?”

Jésù Jí Òkú Lásárù Dìde

38. Nígbà náà ni Jésù tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.

39. Jésù wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”Màtá, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ijọ́ kẹrin tí ó tí kú.”

40. Jésù wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ ó rí ògo Ọlọ́run?”

41. Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.

42. Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”

43. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lásárù, jáde wá.”

44. Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.Jésù wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó má a lọ!”

Àwọn Olórí Pinnu Láti Pa Jésù

45. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Màríà, tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe, ṣe gbà á gbọ́.

46. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe.

47. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé,“Kínni àwa ń ṣe? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.

48. Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Rómù yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”

49. Ṣùgbọ́n Káyáfà, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!

50. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó sàǹfàní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má baà ṣègbé.”

51. Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:

52. Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jésù yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà:

53. Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

54. Nítorí náà Jésù kò rìn ní gbangba láàárin àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbéríko kan tí ó sún mọ́ ihà, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Éfúráímù, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

55. Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì sún mọ́ etílé: ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbéríko sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́.

56. Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jésù, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹ́mpílì, wí pé, “Ẹ̀yin ti rò ó sí? Pé kì yóò wá sí àjọ?”

57. Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn baà lè mú un.