orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jákọ́bù 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa,Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káà kiri, orílẹ̀-èdè.Àlàáfíà.

Àwọn Ìṣòro Àti Àwọn Ìdẹwò

2. Ẹ̀yin ara mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdẹwo ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;

3. Nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdẹwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣisẹ́ sùúrù.

4. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò se aláìní ohunkóhun.

5. Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá bèèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyè méjì dàbí ìgbì omi òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

7. Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa;

8. Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìllèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

9. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga.

10. Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ.

11. Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru mímú ó sì gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànú, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.

12. Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdẹwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

13. Kí ẹnikẹ́ni tí a dẹwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnìkẹ́ni wò;

14. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ.

15. Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán a bí ikú.

16. Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́.

17. Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

18. Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

Gbígbọ́ Àti Ṣíṣe Ọ̀rọ̀ Náà

19. Kí ẹmọ èyí, ẹ̀yin ara mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn kí ó si lọ́ra láti bínú;

20. Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

21. Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburútí ó gbilẹ̀ yíka, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22. Ẹ maa kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rà náà lásán, kí ẹ má baà tipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣse ohun tí ó sọ.

23. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú díńgí

24. Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti sàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójú kan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

25. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

26. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán.

27. Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojú tó àwọn aláìní-baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láì lábàwọ́n kúrò nínú ayé.