Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 6:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí ó sì sí èdìdì kéjì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!”

4. Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.

5. Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹ́tà, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, Wá, wò ó. Mo sì wò ó, sì kíyèsí i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí ni ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.

6. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n àlìkámà kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà-bálì mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsí i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.

7. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹ́rin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó.

8. Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹ̀ṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdá mẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.

9. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìmú:

10. Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, ẹ̀mí mímọ́ àti olóòótọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?”

11. A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí ó ti pa bí wọn, yóò fi dé.

12. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfa mo sì rí i, sì kíyèsí i, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; ọ̀run sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òsùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀;

13. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.

14. A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùsù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

Ka pipe ipin Ìfihàn 6