Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 5:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì wá, o sì gbà á ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.

8. Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú háàpù kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́.

9. Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:nítorí tí a tí pa ọ,ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá:

10. Ìwọ sì tí ṣe wọ́n ni ọba àti àlùfáà sì Ọlọ́run wá:wọ́n sì ń jọba lórí ilẹ̀ ayé.”

11. Èmi sì wò, mo sì gbọ́ ohùn àwọn ańgẹ́lì púpọ̀ yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn ẹ̀dá alààyè náà àti àwọn àgbà náà ká: Iye wọn sì jẹ́ ẹgbàárun ọ̀nà ẹgbàarún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún.

12. Wọn ń wí lóhùn rara pé:“Yíyẹ ni Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà tí a tí pa,láti gba agbára,àti ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n, àti ipá, àti ọlá,àti ògo, àti ìbùkún.”

13. Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé,“Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára,fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntànnáà láé àti láéláé.”

14. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé, “Àmín!” Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé.

Ka pipe ipin Ìfihàn 5