Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 4:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹ̀dá kínní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kéjì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹ́rin sì dàbí ìdì tí ń fò.

8. Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé:“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́,Olúwa Ọlọ́run Olódùmare,tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”

9. Nígbà tí àwọn ẹ̀dá aláàyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láàyè láé àti láéláé.

10. Àwọn àgbà mẹ́rinlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láàyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:

11. “Olúwa, ìwọ ni o yẹláti gba ògo àti ọlá àti agbára:nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ niwọn fi wà tí a sì dá wọn.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 4