Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 2:7-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìye nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrin Párádísè Ọlọ́run.

8. “Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ní Símírínà Kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni-ìṣáájú àti ẹni-ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè:

9. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì.

10. Máṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsí i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túúbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ sa se olóòtọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ

11. Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá sẹ́gun kì yóò farapa nínú ikú kejì.

12. “Àti sì Ańgẹ́lì ìjọ ni Págámọ́sì Kọ̀wé:Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní ídà mímú olójú méjì,

13. Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Sàtánì wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Áńtípà ẹlẹ́rì mi, olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrin yín, níbi tí Sàtánì ń gbé.

14. Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.

15. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikoláétanì pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra.

16. Nítorí náàonúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsinyìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.

17. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi mánà tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.

18. “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

19. Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ.

20. Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ: Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà.

Ka pipe ipin Ìfihàn 2