Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 19:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:“Halelúyà!Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá agbára,

2. nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

3. Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:“Halelúyà!Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

4. Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:“Àmín, Halelúyà!”

5. Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti èwe àti àgbà!”

6. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:“Halelúyà!Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.

7. Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,kí a sì fi ògo fún un.Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,aya rẹ̀ sì ti múra tán.

8. Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

9. Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè-alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10. Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jésù mú: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jésù ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 19