Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:36-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Íjíbítì, àti ni òkun pupa, àti ni ihà ní ogójì ọdún.

37. “Èyí ni Mósè náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’

38. Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú ańgẹ́lì náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sínáì, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.

39. “Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì;

40. Wọ́n wí fún Árónì pé ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ ọ̀nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mósè yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’

41. Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rúbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn se.

42. Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:“ ‘Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún miní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

43. Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gba ojúbọ Mólókù,àti ìràwọ̀ Ráfánì òrìṣà yín,àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ.Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Bábílónì.’

44. “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijú. Èyí tí a se gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mósè sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí ó ti rí.

45. Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì.

46. Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.

47. Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un,

48. “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

49. “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?ni Olúwa wí.Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi?

50. Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’

51. “Ẹ̀yin ọlọ́rùn-líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yín rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!

52. Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa.

53. Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn ańgẹ́lì ti fi fún ni, tí ẹ kò sí pa á mọ́.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7