Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:29-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Mósè sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Mídíànì, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.

30. “Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Mósè ní ijù, ní òkè Sínáì, nínú ọ̀wọ́ iná ìgbẹ́.

31. Nígbà tí Mósè sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i,

32. Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù,’ Mósè sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dàṣà láti wò ó mọ́.

33. “Olúwa sì wí fún un pé, ‘Tú bátà rẹ kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ, nitorí ibi tí ìwọ gbé dúró sí yìí ilẹ̀ mímọ́ ni.

34. Ní rírí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsìn yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì.’

35. “Mósè náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ ańgẹ́lì, tí ó farahàn án ní ìgbẹ́, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè.

36. Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Íjíbítì, àti ni òkun pupa, àti ni ihà ní ogójì ọdún.

37. “Èyí ni Mósè náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’

38. Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú ańgẹ́lì náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sínáì, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.

39. “Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì;

40. Wọ́n wí fún Árónì pé ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ ọ̀nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mósè yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’

41. Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rúbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn se.

42. Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé:“ ‘Ẹ̀yin hà mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún miní ogójì ọdún ní ijù bí, Ìwọ ilé Ísírẹ́lì?

43. Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gba ojúbọ Mólókù,àti ìràwọ̀ Ráfánì òrìṣà yín,àwọn òrìṣà tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ.Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Bábílónì.’

44. “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijú. Èyí tí a se gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mósè sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí ó ti rí.

45. Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Jóṣúà wá sí ilẹ̀-ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókó Dáfídì.

46. Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7