Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:15-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti ẹní kí òjìji Pétérù ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ.

16. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.

17. Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlúfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sádúsì wọ̀.

18. Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn àpósítélì wọn sì fi wọ́n sínú túbú.

19. Ṣùgbọ́n ní òru, áńgẹ́lì Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.

20. Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹ́ḿpìlì kí ẹ sì máa sọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́ré fún àwọn ènìyàn.”

21. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ḿpílì lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpèjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn àpósítélì wá.

22. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùsọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn pàda wá, wọn sí sọ fún wọn pé,

23. “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùsọ́ dúró lóde níwájú ilẹ́kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa sí ilẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.”

24. Nígbà tí olórí ẹ̀sọ́ tẹ́ḿpílì àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.

25. Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹ́ḿpílì, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.”

26. Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olúsọ́, ó sì mú àwọn àpósítélì wá. Wọn kò fi ipá múwọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.

27. Nígbà tí wọn sì mú àwọn àpósítélì dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlúfáà sì bi wọ́n léèrè.

28. Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni. Ṣíbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerúsálémù, ẹ sì ń pete àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5