Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹ́ḿpílì lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpèjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn àpósítélì wá.