Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:28-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣẹ.

29. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsí ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

30. Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradà, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jésù Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

31. Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọ pọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

32. Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì sí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìsọ̀kan.

33. Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.

34. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.

35. Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ àwọn àpósítélì, wọn sì ń pín fún olukúlúkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.

36. Àti Jóṣéfù, tí a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì sọ àpèlé rẹ̀ ní Bánábà (ìtúmọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Léfì, àti ará Sáípúrọ́sì.

37. Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4