Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:24-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n fi ọkàn kan gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run, wọ́n sì wí pé, “Olúwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run àti ayé, àti òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

25. Ìwọ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ti ẹnu Dáfídì baba wa ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé:“ ‘E é ṣe tí àwọn kéférì fi ń bínú,àti tí àwọn ènìyàn ń gbérò ohun asán?

26. Àwọn ọba ayé dìde,àti àwọn ìjòyè kó ara wọnjọ sí Olúwa,àti sí Ẹni-Àmìn òróró rẹ̀.’

27. Àní nítòótọ́ ní Hẹ́rọ́dù, àti Pọ́ńtíù Pílátù, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jésù Ìrànṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi òróró yàn,

28. Láti ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ àti ìmọ̀ rẹ̀ ti pinnu ṣáájú pé yóò ṣẹ.

29. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, Olúwa, kíyèsí ìhàlẹ̀ wọn; kí ó sì fi fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà ńlá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

30. Kí ìwọ sì fi nína ọwọ́ rẹ ṣe ìmúláradà, àti kí iṣẹ́ ìyanu máa ṣẹ̀ ní orúkọ Jésù Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ.”

31. Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọ pọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

32. Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì sí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìsọ̀kan.

33. Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.

34. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.

35. Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ àwọn àpósítélì, wọn sì ń pín fún olukúlúkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4