Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?

13. Ọlọ́run Ábúráhámù, àti ti Ísáàkì, àti ti Jákọ́bù, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jésù ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀.

14. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin sẹ́ Ẹni-Mímọ́ àti Olóòtọ̀ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.

15. Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.

16. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.

17. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe.

18. Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti se ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kírísítì rẹ̀ yóò jìyà.

19. Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,

20. àti kí ó baà lè rán Kírísítì tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jésù.

21. Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti sẹ̀.

22. Mósè wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín.

23. Yóò sì se, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátapáta kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’

24. “Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Sámúẹ́lì wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú.

25. Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Ábúráhámù pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3