Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 24:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àwọn Júù pẹ̀lú sì fi ohùn sí i wí pé, ní òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.

10. Nígbà tí baálẹ̀ ṣẹ́wọ́ sì i pé kí ó sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù sì dáhùn wí pe: “Bí mo tí mọ̀ pé láti ọdún mélòó yìí wá, ní ìwọ tí ṣe onídájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, nítorí náà mo fi tayọ̀ tayọ̀ wí tí ẹnu mi.

11. Ìwọ pẹ̀lú sì ní òye rẹ̀ pé, ìjejìlá ni mo lọ sí Jerúsálémù láti lọ jọ́sìn.

12. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùfisùn mi kò rí mi kí ń máa bá ẹnìkẹ́ni jiyàn nínú téḿpílì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ru àwọn ènìyàn sókè nínú ṣínágọ́gù tàbí ní ibikíbi nínú ìlú:

13. Bẹ́ẹ̀ ní wọ́n kò lè fi ìdí ẹ̀sùn múlẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí wọn fi mí sùn sí nísinsìn yìí.

14. Ṣùgbọ́n, èmí jẹ́wọ́ fún ọ pé, èmi ń sin Ọlọ́run àwọn baba wa gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń tẹ̀le ọ̀nà tí wọ́n ń pè ni ìyapa-ìsìn. Èmi ń gbá gbogbo nǹkan ti a kọ sínú ìwé òfin gbọ́, àti tí a kọ sínú ìwé àwọn wòlíì,

15. mo sí ní ìrètí kan náà nínú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn tìkaráwọn jẹ́wọ́ pẹ̀lú, wí pé àjíǹde òkú ń bọ̀, àti tí olóòtọ́, àti tí aláìsòótọ́.

16. Nínú èyí ni èmi sì ti ń gbìyànjú láti ní ẹ̀rí-ọkàn tí kò lẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, àti sí ènìyàn nígbà gbogbo.

17. “Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdun púpọ̀, mo wá sí Jerúsálẹ́mù láti mu ẹ̀bún wá fún àwọn ẹ̀nìyàn mi fún aláìní àti láti fi ọrẹ lélẹ̀.

18. Nínú ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, wọ́n rí mí nínú iyẹ̀wù tẹ́ḿpílì, bí mo ti ń parí ètò ìwẹ́nú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ní àárin àwùjọ ènìyàn, tàbí pẹ̀lú ariwo.

19. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan láti ẹkùn Éṣíà wà níbẹ̀, àwọn tí ì bá wà níhìn-ín yìí níwájú rẹ, kí wọn já mi nírọ́, bí wọ́n bá ní ohunkohun sí mi.

20. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tíkarawọn sọ iṣẹ́ búburú tí wọ́n rí lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀.

21. Bí kò ṣe tí gbolóhùn kan yìí, tí mo kégbe rẹ̀ ṣíta nígbà tí mo dúró láàrin wọn: ‘Èyí ni tìtorí àjíǹde òkú ni a ṣe ba mi wíjọ́ lọ́dọ̀ yín lóni yìí!’ ”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 24