Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fí di òní yìí.”

2. Nígbà yìí ni Ananíyà olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Pọ́ọ̀lù pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.

3. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ogiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan-an alára rú òfin nípa pípaṣẹ pé kí a lù mí!”

4. Àwọn tí ó dúró tì Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”

5. Pọ́ọ̀lù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù sàkíyèsí pé, apákan wọn jẹ́ Sádúsì, apákan sì jẹ́ Farisí, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisí, ọmọ Farisí sì ni èmi: mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

7. Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrin àwọn Farisí àti àwọn Sádúsì: àjọ sì pín sì méjì.

8. Nítorí tí àwọn Sádúsì wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí ańgẹ́lì, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisí jẹ́wọ́ méjèèjì:

9. Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisí dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí áńgẹ́lì kan tàbí ẹ̀mí kan ń baà sọ̀rọ̀?”

10. Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Pọ́ọ̀lù má baà di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrin wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

11. Ní òru ijọ́ náà Olúwa dúró tì Pọ́ọ̀lù, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerúsálémù, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Róòmù pẹ̀lú.”

12. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, awọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Pọ́ọ̀lù:

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23