Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fí di òní yìí.”

2. Nígbà yìí ni Ananíyà olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Pọ́ọ̀lù pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.

3. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ogiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan-an alára rú òfin nípa pípaṣẹ pé kí a lù mí!”

4. Àwọn tí ó dúró tì Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”

5. Pọ́ọ̀lù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí Pọ́ọ̀lù sàkíyèsí pé, apákan wọn jẹ́ Sádúsì, apákan sì jẹ́ Farisí, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisí, ọmọ Farisí sì ni èmi: mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”

7. Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrin àwọn Farisí àti àwọn Sádúsì: àjọ sì pín sì méjì.

8. Nítorí tí àwọn Sádúsì wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí ańgẹ́lì, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisí jẹ́wọ́ méjèèjì:

9. Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisí dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí áńgẹ́lì kan tàbí ẹ̀mí kan ń baà sọ̀rọ̀?”

10. Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Pọ́ọ̀lù má baà di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrin wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

11. Ní òru ijọ́ náà Olúwa dúró tì Pọ́ọ̀lù, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerúsálémù, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Róòmù pẹ̀lú.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23