Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12:7-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Sì wò ó, ańgẹ́lì Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ́ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Pétérù.

8. Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!”

9. Pétérù sì jáde, ó ń tọ ọ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèbí òun wà lójú ìran.

10. Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

11. Nígbà tí ojú Pétérù sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán ańgẹ́lì rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Héródù àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń rétí!”

12. Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Johánù, tí àpélè rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ pejọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.

13. Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Ródà wá láti dáhùn.

14. Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Pétérù, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sí sọ pé, Pétérù dúró ní ẹnu-ọ̀nà.

15. Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Ańgẹ́lì rẹ̀ ni!”

16. Ṣùgbọ́n Pétérù ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n.

17. Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jákọ́bù àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.

18. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrin àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó débá Pétérù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12