Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11:14-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ fún ọ, nípa èyí tí a ó fi gba ìwọ àti gbogbo ilé rẹ là.’

15. “Bí mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sì sọ, Ẹ̀mi Mímọ́ sì bà lé wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ni àtètèkọ́ṣe.

16. Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Jòhánù fi omi bamitíìsì nítóòtọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì yín.’

17. Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jésù Kírísítì Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”

18. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run ógo wí pé, “Ǹjẹ́ Ọlọ́run fi ìrònúpíwàdà sí ìyè fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú!”

19. Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri ní ti inúnibíni tí ó dìde ní ti Sítéfánù, wọ́n rìn títí de Fonísíà, àti Kípíru, àti Ańtíókù, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù.

20. Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Sáípúrọ́sì àti Kírénè; nígbà tí wọ́n dé Áńtíókù, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Hélénì pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù Jésù Olúwa.

21. Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.

22. Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerúsálémù; wọ́n sì rán Bánábà lọ títí dé Áńtíókù;

23. Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.

24. Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.

25. Bánábà sì jáde lọ sí Tásọ́sì láti wá Ṣọ́ọ̀lù,

26. nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Áńtíókù. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọ pọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Áńtíókù ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kírísítìánì.”

27. Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn wòlíì sì ti Jerúsálémù sọ̀kalẹ̀ wá sí Áńtíókù.

28. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, ti a ń pè ni Ágábù sí dìde, ó ti ipa Ẹ̀mí sọ pé, ìyàn ńlá yóò mú yíká gbogbo ilẹ̀ Róòmù. (Èyí sì ṣẹlẹ̀ nígbà ìsèjọba Kíláúdíù.)

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11