Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílípì 1:14-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.

16. Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere.

17. Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni.

18. Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì. Èyí sì ni ayọ̀ mi.Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì máa yọ̀;

19. Nítorí tí mo mọ̀ pé nípa àdúrà yín àti ìrànlọ́wọ́ tí Ẹ̀mí Jésù Kírísítì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò padà já sí ìtúsílẹ̀ mi.

20. Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi.

21. Nítorí, níti èmi, láti wa láàyè jẹ́ Kírísítì, láti kú jẹ́ èrè.

22. Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì wà láàyè nínú ara, èyí yóò jásí èrè fún iṣẹ́ mi. Síbẹ̀, kíni èmí yóò yàn? Èmi kò mọ̀?

23. Mo wà ní agbede méjì. Mo fẹ́ràn láti wà pẹ̀lú Kírísítì, èyí tí ó dára jùlọ.

24. Ṣùgbọ́n ó ṣe iyebíye fún yín kí èmi kí ó wà nínú ara.

25. Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́,

26. kí ìbádàpọ̀ mi pẹ̀lú yín lẹ́ẹ̀kan si le ru ayọ̀ yín sókè nínú Kírísítì nítorí mi.

27. Ohun tó wù kí ó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí iṣẹ́ yín wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyìnrere Kírísítì. pé yálà bí mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin sì jùmọ̀ n jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìn rere, pẹ̀lú ọkàn kan;

28. láìsí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn tí ó dojúkọ yin lọ́nà kanna. Èyí sì jẹ́ àmì fún wọn pé a ó pa wọ́n run, a ó sì gbà yín là —èyí tí Ọlọ́run yí ó ṣe.

29. Nítorí a ti fi fún yín nítorí Kírísítì, kì í ṣe láti gbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.

30. Nípa níní ìjàkadì kan náà tí ẹ̀yin ti rí tí èmi là kọjá, ti ẹ sì gbọ́ nísinsinyìí pé mo sì wà nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Fílípì 1