Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílípì 1:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ẹlẹ̀ sí mi já sí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere.

13. Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangban sí gbogbo àwọn ẹ̀sọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kírísítì.

14. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.

16. Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere.

17. Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni.

18. Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì. Èyí sì ni ayọ̀ mi.Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì máa yọ̀;

19. Nítorí tí mo mọ̀ pé nípa àdúrà yín àti ìrànlọ́wọ́ tí Ẹ̀mí Jésù Kírísítì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò padà já sí ìtúsílẹ̀ mi.

20. Ó jẹ́ ìfojúsọ́nà àti ìrètí mi pé ojú kì yóò tì mí nínú ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi ó ní ìgboyà nísinsìnyìí bí ti ìgbà gbogbo pé ní yíyè, tàbí ní kíkú, a ó gbé ga lára mi.

21. Nítorí, níti èmi, láti wa láàyè jẹ́ Kírísítì, láti kú jẹ́ èrè.

22. Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì wà láàyè nínú ara, èyí yóò jásí èrè fún iṣẹ́ mi. Síbẹ̀, kíni èmí yóò yàn? Èmi kò mọ̀?

Ka pipe ipin Fílípì 1