Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Fílípì 1:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù àti Tìmótíù, àwọn ìránṣẹ́ Jésù Kírísítì,Sí gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù tí ó wà ní Fílípì, pẹ̀lú àwọn bíṣọ́ọ̀bù àti àwọn díákónì

2. Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jésù Kírísítì.

3. Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín:

4. Nínú gbogbo àdúrà mi fún-un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà,

5. nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìyìn rere láti ọjọ́ kìn-ín-ni wá títí di ìsinsinyìí.

6. Ohun kan yìí ṣáà dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ Jésù Kírísítì:

7. Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹmúlẹ̀ ìyìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábàápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi.

8. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jésù Kírísítì.

9. Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti ṣíwájú síi nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,

10. kí ẹ̀yin kí ó lè dà ohun tí ó dára jùlọ yàtọ̀ mọ̀, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ọjọ́ Kírísítì,

11. tí ẹ sì kún fún èso òdodo tí ó ti ọ́dọ̀ Jésù Kírísítì wá—fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

12. Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ẹlẹ̀ sí mi já sí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìyìnrere.

13. Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangban sí gbogbo àwọn ẹ̀sọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kírísítì.

14. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni ẹ ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run síi pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kírísítì, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é.

16. Àwọn ti ìkẹ́yìn n fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a ó gbé mi dìde fún ìgbèjà ìyìn rere.

17. Ṣùgbọ́n àwọn ti ìṣáájú ẹ̀wẹ̀ ń fi ìlépa ara ẹni ń wàásù Kírísítì, kì í ṣe pẹ̀lú òótọ́ inú, wọn ń gbérò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi ni.

18. Ṣùgbọ́n ohun tí ó sa ṣe pàtàkì ni pé, bóyá a wàásù pẹ̀lú ètè tó dára tàbí èyí tí kò dára, a ṣsá ń wàásù Kírísítì. Èyí sì ni ayọ̀ mi.Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì máa yọ̀;

Ka pipe ipin Fílípì 1