Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 2:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má baà gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan.

2. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn ańgẹ́lì sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀sẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i,

3. kí ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnraarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.

4. Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

5. Nítórí pé, kì í ṣe abẹ́ ìsàkóso àwọn ańgẹ́lì ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.

6. Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?

7. Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ;ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:

8. Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”Ní ti fí fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Ṣíbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀

9. Ṣùgbọ́n àwa rí Jésù ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jésù, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

10. Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe Balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.

11. Nítorí àti ẹni tí ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.

12. Wí pé,“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,ni àárin ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 2