Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 13:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrin gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléérí: Nítorí àwọn àgbérè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ̀jọ́.

5. Ki ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí oun tìkararẹ̀ ti wí pé,“Èmi kò jẹ fi ọ́ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

6. Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,“Olúwa ni oluranlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;kínni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

7. Ẹ máa rántí àwọn ti wọn jẹ́ aṣáájú yín, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà-ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn.

8. Jésù Kírísítì ọ̀kan náà ni lánà, àti lóní, àti títí láé.

9. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.

10. Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.

11. Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ̀yìn ibùdó.

12. Nítorí náà Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ̀yìn ìbodè.

13. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ̀yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.

14. Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níyin, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.

15. Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 13