Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń réti, ìjeri ohun tí a kò rí.

2. Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà (atijọ́) ní ẹ̀rí rere.

3. Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.

4. Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábélì rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Káínì lọ, nípa èyí tí a jẹ̀rí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́ri ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.

5. Nípa ìgbàgbọ́ni a sì Énókù nípò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sí rí i, nítorí ti Ọlọ́run ṣi i nípò padà: nítorí ṣaáju ìsìpo padà rẹ̀, a jẹ́ri yìí si i pé o wu Ọlọ́run.

6. Ṣùgbọ́n làísí ìgbàgbọ́ kò ṣeéṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè sàì gbàgbọ́ pé o ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

7. Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóàh, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tíì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ̀bí, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

8. Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábúráhámù, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè.

9. Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Ísáákì àti Jákọ́bù, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀:

10. Nítorí tí ó ń rétí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; ọ èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí o si kọ́.

11. Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà tìkararẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọja ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérì sí olootọ́.

12. Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí ìyanrìn etí òkun láìníyè.

13. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o kú ní ìgbàgbọ́, láì rí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, ti wọn si gbá wọn mú, tí wọn sì jẹ̀wọ́ pé àlejò àti àtìpó ni àwọn lórí ilẹ́ ayé.

14. Nítorí pé àwọn tí o ń ṣọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11