Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 5:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kírísítì, ó di ẹ̀dá titun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsí i, ohun titun ti dé.

18. Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì típaṣẹ̀ Jésù Kírísítì bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa.

19. Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kírísítì, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́.

20. Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kírísítì, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín nípò Kírísítì, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,”

21. Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 5