Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 6:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábàápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú.

3. Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jésù Kírísítì Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu,

4. Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkankan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀-búburú wá,

5. Àti ọ̀rọ̀ àyípo àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, ti wọn ṣèbí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.

6. Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni.

7. Nítorí a kò mu ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ.

8. Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yóò tẹ́ wa lọ́rùn.

9. Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹkùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa-ni-lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.

10. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn sìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.

11. Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrú, ìwà tútù.

12. Má a ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.

13. Mo paṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,

14. Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 6