Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 6:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnikejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìsòótọ́ bí, bí kò se níwájú àwọn ènìyàn mímọ́?

2. Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpaṣẹ̀ yín ni a ti ṣe ìdájọ́ ayé, kí ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrin ara yín.

3. Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ańgẹ́lì ní? Mélòómélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí.

4. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ yan àwọn tí ó kéré jù nínú ìjọ láti dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.

5. Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín, Ṣe ó see se kí a máa rín ẹnìkan láàrin yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe idájọ́ èdè àìyedè láàrin àwọn onígbàgbọ́?

6. Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.!

7. Ǹjẹ́ nísinsinyìí, àbùkù ni fún un yín pátapáta pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kí ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kí ní dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?

8. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.

9. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìsòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀

10. tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mútí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

11. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ̀n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 6