Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 3:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Wàrà ni mo ti fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ; nítorí ẹ kò í tí le gbà á nísinsin yìí náà, ẹ kò í tí le gbà a.

3. Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà sì wà láàrin ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí?

4. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Àpólò.”

5. Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Àpólò ha jẹ́, kí ni Pọ́ọ̀lù sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípaṣẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olukúlúkù.

6. Èmi gbìn, Àpólò ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá.

7. Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá.

8. Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bomi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.

9. A ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, ẹ̀yin pàápàá sì jẹ́ ọgbà ohun ọ̀gbìn fún Ọlọ́run, kì í ṣe fún wa, ilé Ọlọ́run ni yín, kì í ṣe ilé tiwa.

10. Nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọ́run tí fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ìpìlẹ̀ ilé lélẹ̀, ẹlòmíràn sì ń mọ lé e, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù kíyèsára bí yóò ṣe mọ ọ́n lé e.

11. Nítorí kò sí ẹlòmíràn tó le fi ìpìlẹ̀ tòótọ́ mìíràn lélẹ̀ ju èyí tí a fi lélẹ̀ àní Jésù Kírísítì ni ìpìlẹ̀ náà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 3