Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 2:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó farasin, ọgbọ́n tí ó ti farapamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.

8. Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀: ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀, wọn kì bá tún kan ọba ògo mọ́ àgbélébùú.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ojú kò tíì rí,etí kò tí í gbọ́,kò sì ọkàn tí ó tí í mọ̀ènìyànohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

10. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mi rẹ̀.Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àsírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ.

11. Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni tó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bíkòse Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnraa rẹ̀.

12. Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.

13. Èyí ni àwa ń wí, kì í e èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí.

14. Ẹnikẹ́ni tí kò bá jẹ́ ti Ẹ̀mí kò lè gba àwọn ohun tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mi Mímọ́, nítorí wọ́n jẹ́ ohun wèrè sí, kò sì le ye e, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn.

15. Ẹni tí ẹ̀mí ń ṣe ìdájọ́ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a kò ti ọwọ́ ènìyàn dá lẹ́jọ́:

16. “Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kírísítì.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 2