Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 2:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ìwáàsu mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí.

5. Kí ìgbàgbọ́ yín kí ó má ṣe dúró lórí ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ó dúró lórí agbára Ọlọ́run.

6. Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàrin àwọn tí a pè; ṣùgbọ́n kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, èyí tí yóò di asán

7. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n ti Ọlọ́run tó farasin, ọgbọ́n tí ó ti farapamọ́, èyí tí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.

8. Èyí ti ẹnikẹ́ni nínú àwọn aláṣẹ ayé yìí kò mọ̀: ìbá ṣe pé wọ́n mọ̀, wọn kì bá tún kan ọba ògo mọ́ àgbélébùú.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ojú kò tíì rí,etí kò tí í gbọ́,kò sì ọkàn tí ó tí í mọ̀ènìyànohun tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí o fẹ́ Ẹ.”

10. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í hàn fún wa nípasẹ̀ Ẹ̀mi rẹ̀.Ẹ̀mí á máa wádìí ohun gbogbo, kódà àwọn àsírí Ọlọ́run tó jinlẹ̀ jùlọ.

11. Ta ni nínú ènìyàn tí ó mọ èrò ọkàn ènìyàn kan, bí kò ṣe ẹ̀mí ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, kò sí ẹni tó mọ àwọn èrò Ọlọ́run, bíkòse Ẹ̀mí Ọlọ́run fúnraa rẹ̀.

12. Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 2