Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 12:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwonisàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

10. Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn Ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀ tí wọn kò rí. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí.

11. Àní, Ẹ̀mi kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

12. Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan soso. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kírísítì tí í ṣe ìjọ.

13. Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitísì gbogbo wa sínú ara kan, ìbáà ṣe Júù, ìbaà ṣe Gíríkì, ìbáà ṣe ẹrú, ìbaà ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

14. Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

15. Tí ẹ̀ṣẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara.

16. Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apákan ara,” èyí kò lènu máa jẹ́ apákan ara mọ́

17. Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú? Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn? Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn?

18. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.

19. Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 12