Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 12:17-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú? Níbo ni a ó ti ma gbọ́ràn? Tí gbogbo ara bá jẹ̀ etí ńkọ́? Ọ̀nà wo la lè gbà gbọ́ òórùn?

18. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.

19. Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ìkanṣoṣo nínú ẹ̀yà-ara, níbo ni ara yóò gbé wà.

20. Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.

21. Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.”

22. Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan-an ni a ko le ṣe aláìnílò.

23. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara ti a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara ti a rò pé yẹ rára ni àwa ń fi ipò ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ.

24. Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ sọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.

25. Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn.

26. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.

27. Gbogbo yín jẹ́ ara Kírísítì, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kírísítì.

28. Àti nínú ìjọ, Olọ́run ti yan àwọn àpósítélì àkọ́kọ́, èkéjì àwọn wòlíì, ẹni ẹ̀kẹta àwọn Olùkọ́, lẹ́yìn náà, àwọn tí ó ní òsìsẹ́ iṣẹ́ ìyanu, lẹ́yin náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmuláradá, àwọn Olùrànlọ́wọ́ àwọn alákòóso àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.

29. Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ àpósítélì bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí?

30. Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Olọ́run fún lẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ̀n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?

31. Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara sàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.Ṣíbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 12