Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 12:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè.

2. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ abọ̀rìṣà, a fà yín lọ sọ́dọ̀ odi òrìṣà, ni ọ̀nà tí ó wù kí a gbà fà yín lọ.

3. Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jésù,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jésù,” bí kò ṣe nípàṣẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

4. Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni.

5. Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni.

6. Onírúurú iṣẹ́-ìranṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n lọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣisẹ́ gbogbo wọn níní gbogbo wọn.

7. Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè.

8. Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn lámọ́ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mimọ́ kan náà ni èyì ti wá.

9. Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwonisàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

10. Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn Ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀ tí wọn kò rí. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí.

11. Àní, Ẹ̀mi kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

12. Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan soso. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kírísítì tí í ṣe ìjọ.

13. Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitísì gbogbo wa sínú ara kan, ìbáà ṣe Júù, ìbaà ṣe Gíríkì, ìbáà ṣe ẹrú, ìbaà ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 12