Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 11:13-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Kí ni ẹ̀yìn fún ra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?

14. Njẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.

15. Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígún, ògo ni ó jẹ́ fùn un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún-ún.

16. Ṣùgbọ́n tí ẹnìkẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní àṣà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrin ìjọ Ọlọ́run.

17. Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá pé jọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.

18. Lọ́nà kínní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrin yín ní ìgbà tí ẹ bá pé jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan.

19. Kò sí àníàní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrin yín, kí àwọn tí ó yanjú láàrin yín le farahàn kedere.

20. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.

21. Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olukúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkèjì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.

22. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kí ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

23. Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Júdásì fi hàn, Olúwa Jésù Kírísítì mú búrẹ́dí.

24. Lẹ́yìn igbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.”

25. Bákan náà ló mu kọ́ọ̀bù ọtí wáìnì lẹ́yìn oúnjẹ, ó sì wí pé, “Kọ́ọ̀bù yìí ní májẹ̀mú titun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”

26. Nítorí nígbákùúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú kọ́ọ̀bù yìí, ni ẹ tún sọ nipa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

27. Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú kọ́ọ̀bù Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 11