Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 10:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arakùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú ihà. Ọlọ́run samọ̀nà wọn nípa rírán ìkùúkù ṣíwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi òkun pupa já.

2. A lè pe eléyìí ní ìtèbọmi sí Mósè nínú ìkùúkù àti nínú omi òkun.

3. Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.

4. Wọ́n mu nínú omi tí Kírísítì fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kírísítì. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú ihà náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.

5. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ lẹ́yin èyí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò ṣe ìgbọ́ràn sí Ọlọ́run. Òun sì pa wọ́n run nínú ihà.

6. Ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́ yìí jásí àpẹrẹ fún wa, kí a má ṣe ní ìfẹ̀ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn nínú ihà.

7. Kí ẹyin má ṣe sin ère òrìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti jó.”

8. Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbérè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan.

9. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n.

10. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

11. Gbogbo àwọn nǹkan tí mo ń wí wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n sì jẹ́ àpẹrẹ, fún wa, wọ́n kọ wọ́n sílẹ̀ bí ikìlọ̀ fún wa láti yàgò kúrò nínú síṣe àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. A kọ èyí sílẹ̀ fún kíkà wa ní àkókò yìí tí aye fi ń lọ sópin.

12. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à subú.

13. Kò sí ìdànwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó ti bá ènìyàn rí, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlórun, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ̀n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ́yin baà lè faradà á.

14. Nítorí náà, ẹ̀yín olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.

15. Èmi ń sọ̀rọ̀ sí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ṣe ìdájọ́ fúnra rẹ̀ ohun tí mo sọ.

16. Ago ìbùkún tí a ń súre sí, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kírísítì bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábàápín nínú ara Kírísítì bi?

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 10