Wọ́n mu nínú omi tí Kírísítì fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kírísítì. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú ihà náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára.